HYMN 176

1.	Baba pa lase lat’Orun wa,

	Ki gbogbo aiye si wariri,

	Fun ‘jo Mimo, tar’Orun wa,

	Ijo yi ni, yio we aiye mo,

	Aje, oso, yio wariri,

	L’abe agbara Mimo yi,

	Awon Angeli si kun f’ayo,

	Iyanu, f’oko ikehin,

	Halleluya fun ise Oluwa.



2.	Igba ikehin na ti de,

	Kristi Jesu yio pada wa,

	Lati wa se ‘dajo aiye,

	Iku Re lori agbelebu,

	Eje ati omi to nsan,

	Kuro ninu iha Mimo Re,

	Ko gbodo lo sorin asan,

	Gbogbo oju yio sit un ri,

	Pelu awon Angeli Mimo Re. 



3.	Kelese ronupiwada,

	F’ojo iwariri nla na,

	Awon angeli yio fun ipe,

	A o ka ile at’Orun,

	Okun yio d’ohun airi mo,

	Awon oku yio ji dide,

	Imiran pelu ayo nla

	Imiran pelu ijiya,

	Elese yio wariri lojo na.



4.	Awon toku f’oro Kristi,

	Awon t’o ru Agbelebu Re,

	Nwon yio ji pelu ogo nla,

	A o wo won laso ogo,

	A o de won lade wura,

	Mariwo ope lowo won,

	Nwon yio fo pade Kristi won,

	Are ki yio si fun won mo,

	Halleluya, li ohun orin won. Amin



English »

Update Hymn