HYMN 182

1.  E KU ayo bla t'Ajinde

     T'Oluwa demi wa si d'oni,

     Ope f'Oluwa to da wa si d'oni,

     Ayo, ayo, wa ti po to,

     Pelu idapo t'awon Angeli.


2.  E yo e yo, ninu Oluwa,

     E ke Kabiyesi s'Oba nla,

     Jesu Kristi bi Oba ojo oni,

     E yo, e yo fun 'gbala wa,

     T'a fi f'aiye ninu Eje Jesu.


3.  E ke Hossanah si Oba wa,

     Oludande Agbaiye jinde,

     Jesu Kristi ni Oba ojo oni,

     Halleluya si Olorun,

     To f'omo Re fun 'gbala araiye.


4.  Ijo Mimo e wole sin,

     Olugbala araiye jinde,

     Awon 'rawo Orun nyin logo,

     O ti j'Oba, Jesu joba agbaiye,

     E jumo sin Jesu. Amin

English »

Update Hymn