HYMN 291

1.	ORO Oluwa ko si yin,

	Latoke Orun wa,

	E mura, ke gbo ipe na,

	Ke si ri ogo na. 


2.	Aiye yi yio lo si opin,

	Ohun gbogbo yio tan,

	Enikeni to gbo oro na,

	Yio si ri ogo na.


3.	Ijo Mimo e tun ra di,

	Ka le kun aye yin,

	Aye ti Jesu wa sile,

	Ti yin ni yio si je.


4.	Ife Oluwa ti po to,

	S’enyin Ijo Mimo,

	E mura ke gb’Oluwa gbo,

	Ke le ri ogo Re.


5.	Eyin, aiye ke mo daju,

	P’asan laiye yi je,

	Oro Oluwa ododo,

	Ni yio je nikehin.


6.	Ade Mimo t’Emi ti pese,

	F’awon to gba mi gbo,

	Awon to gbagbo yio dade na,

	Lati sogo kehin. Amin

English »

Update Hymn