HYMN 377

1.	E je k’a fope fun Baba,

	Jehovah Olodumare,

	Eleda Orun aiye,

	To da wa si di oni. 


2.	On lo da Orun meje,

	Ati ile meje pelu,

	Orun ati Osupa,

	Ti ntanmole yi wa ka.


3.	O fi onje fun gbogbo eda,

	Eiye iwo to nfo koja,

	Ti k’ogbin, ti ko kore,

	Ati eranko igbe.


4.	E ba wa, yin Oluwa,

	Ologo ti ko nipekun,

	Oba okiki Imole,

	Oba Olusegun wa.


5.	Jehovah, Mimo, Mimo, Mimo,

	F’oju rere Re wo wa,

	Ko si ma Samona wa,

	Ninu Ijo Mimo yi.


6.	Jesu Kristi, Olugbala,

	F’igbala Re kari wa,

	Ka le bo ninu ese,

	Nitori isun eje Re.


7.	Michael Mimo, Balogun wa,

	Olugbeja ‘won eni Mimo,

	Gbe ida Re soke fun wa,

	Lati segun emi esu.


8.	Ogo ni fun Baba l’Orun,

	Ogo ni fun Omo Re,

	Ogo ni fun Emi Mimo,

	Meta lokan aiyeraiye. Amin

English »

Update Hymn