HYMN 407

1.	Wa pelu wa, sure fun wa, oba Mimo

	Se ri ‘bukun Re s’ori wa,

	Ka ma bisi, ka ma re si, ni Ijo Mimo

	K’Alleluya le j’orin wa. 


2.	Michael Mimo, gbe’da soke ka le bori

	Gbogbo ota Ijo Mimo

	K’o ko kehin le w’aiye mo lase Kristi,

	Ka le jumo ke Hossanah.


3.	Ka boyun bi, kawon agan towo b’osun

	Ka ma rago, ka ma pose

	Ka je sekun, l’alafia ninu ayo nla.

	Ki Iye, Igbala je pin wa. Amen

English »

Update Hymn