HYMN 428

1.	Jehovah Onibu Ore,

	Ro ‘jo Ibukun Mana Re,

	L’arin wakati yi,

	Ibukun t’aiye ko le fi fun ni,

	Ire to so Okun,

	Di ona fun awon omo Israel,

	Wa lana Ibukun rere fun wa,

	Wa se ti wa ni re.


2.	Ire to pase fun awon,

	Eiye Iwo lati wa fi,

	Akara at’eran didun,

	Bo Woli Elijah,

	Leba odo Jordan,

	Jowo ranti,

	Awa ti nke pe O,

	Ki o si fi jije at mimu,

	L’ona awamaridi bow a ti Re,

	Oba Onibu Ore.


3.	Oba to gbekun Elizabeth,

	Awa omo Re nw’oju Re,

	F’omo rere se ranti wa,

	Oba Olupese,

	Jesu Oba Oluwosan Mimo,

	Wa wo awa ti Re san,

	Ka’wa le fi orin ayo sin O,

	Ninu Ijo Mimo Re lat’Orun wa,

	Olu f’ayo fun mi. Amin

English »

Update Hymn