HYMN 554

1.	Baba ka mi mo won,

	Ki n le j’ogun iye,

	Ka mi mo awon ti orun

	Ki n le j’ogun iye.


2.	Se mi ni ayanfe,

	Ki n le j’ogun iye

	Baba se mi ni ayanfe

	Ki n le j’ogun iye.


3.	Enyin Ijo Mimo

	Oko ‘kehin l’eyi

	E mura giri lekoko

	K’oko ‘kehin to kun 


4.	Enyin ayanfe mi,

	E yin Mi lotito

	E mura giri lati sin

	Ke le j’ogun iye


5.	Or’ofe Re Baba

	Ko ba w’omo Re gbe

	K’emi olutunu orun

	Ko ma s’amona wa.  Amin

English »

Update Hymn