1. Maleka Mimo t’orun,
Nwon ti t’Orun sokale,
Lati wa sure fun wa,
Ninu ijo Mimo
2. Enyin omo ijo Mimo
Mura lati se ife Re
Nitori o mbo Kankan
Lati be wa wo.
3. Gbogbo ‘enyin Oluponju,
E korin ke ho f’ayo
Nitori oluwa mbo
Yio da yin nide.
4. Ayo wa yio ti po to
Nikehin ni ijoba Oruun
Bi awa ba le mura
S’ise Oluwa.
5. Enyin o sise Oluwa
Mura lati sise na
Nitori ere nyin po
Li oke Orun. Amin